1Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA: tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà Rẹ̀
2Nítorí tí ìwọ yóò jẹ isẹ́ ọwọ́ Rẹ ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
3Obìnrin Rẹ yóò dà bí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárin ilé Rẹ; àwọn ọmọ Rẹ yóò dà bí igi olífì tí ó yí tábìlì Rẹ ká.
4Kíyèsíi pé, bẹ́ẹ̀ ni a o bù síi fún ọkùnrin náà, tí o bẹ̀rù OLÚWA.