1Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá ni kí Ísírẹ́lì kí ó wí nísinsinyí
2Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá; ṣíbẹ̀ wọn kò tíì borí mi.
3Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì là aporo wọn gígùn.
4Olódodo ní OLÚWA: ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.
4
5Kí gbogbo àwọn tí ó korìíra Síónì kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
6Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀ tí ó gbẹ dànù kí o tó dàgbà sókè:
7Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ Rẹ̀: bẹ́ẹ̀ ní ẹni tí ń di ìtì, kó kún apá Rẹ̀.
8Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kó wí pé, ìbùkún OLÚWA kí o pẹ̀lú yín: àwa ń súre fún yin ní orúkọ OLÚWA.