Ìwé Sáàmù 13:1-6 BYB2014 - Bible AI

1Yóò ti pẹ́ tó, OLÚWA? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé? yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú Rẹ pamọ́ fún mi?

2Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà, àti ní ojojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi? Yóò ti pẹ́tó tí àwọn ọ̀ta mi yóò máa borí mi?

2

3Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, OLÚWA Ọlọ́run mi. Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sùn oorun ikú;

4Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun Rẹ̀,” àwọn ọ̀ta mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

4

5Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà; ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà Rẹ.

6Èmi ó kọrin sí OLÚWA, nítorí ó dára sí mi.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>