Ìwé Sáàmù 130:1-8 BYB2014 - Bible AI

1Láti inú ibú wá ní èmi ń képè ọ OLÚWA

2OLÚWA, gbóhùn mi, jẹ́ kí etí Rẹ̀ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

2

3ⓐ  OLÚWA, ìbáṣe pé kí ìwọ kí o máa ṣàmì ẹ̀ṣẹ̀, OLÚWA, tà ni ìbá dúró.

4Nítorí ìdàríjìn wà lọ́dọ̀ Rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù Rẹ.

4

5Èmi dúró de OLÚWA, ọkàn mi dúró, àti nínú ọ̀rọ̀ Rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí

6Ọkàn mi dúró de OLÚWA, ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ, àní ju àwọn ti ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

6

7Ísírẹ́lì, ìwọ ní ìrètí ní ti OLÚWA: nítorí pé lọ́dọ̀ OLÚWA ni àánú wà, àti lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáńdè wà.

8Òun ó sì dá Ísírẹ́lì ní ìdè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ gbogbo.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>