1OLÚWA, rántí Dáfídì nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀:
2Ẹni tí ó ti búra fún OLÚWA, tí ó sì ṣe ìlèrí fún Alágbára Jákọ́bù pé.
3Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gùn orí àkéte mi:
4Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
5Títí èmi ó fi rí ibi fún OLÚWA, ibùjókòó fún Alágbára Jákọ́bù.
5
6Kíyèsí i, àwa gbúroo Rẹ̀ ni Éfúrátà: àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
7Àwa ó lọ sínú àgọ́ Rẹ̀: àwa ó máa sìn níbi àpótí-ìtìsẹ̀ Rẹ̀
8OLÚWA, dìde sí ibi ìsinmi Rẹ: ìwọ, àti àpótí agbára Rẹ.
9Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà Rẹ: kí àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
9
10Nítorí tí Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ Má ṣe yí ojú ẹni-òróró Rẹ padà.
11ⓐ OLÚWA ti búra nítòótọ́ fún Dáfídì: Òun kí yóò yípadà kúrò nínú Rẹ̀, nínú irú ọmọ inú Rẹ ní èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ Rẹ.
12Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókoo lórí ìtẹ́ Rẹ láéláé.
12
13Nítorí tí OLÚWA ti yan Síónì: ó ti fẹ́ẹ fún ibùjókòó Rẹ̀.
14Èyí ní ibi ìsinmi mí láéláé: níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé: nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
15Èmi yóò bùkún oúnjẹ Rẹ̀ púpọ̀ púpọ̀: èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà Rẹ̀ lọ́rùn.
16Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlúfáà Rẹ̀: àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
16
17Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwọ Dáfídì yọ̀, èmi ti ṣe ìlànà fítílà kan fún ẹni òróró mi.
18Àwọn ọ̀tá Rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀: ṣùgbọ́n lára Òun tìkararẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.