Ìwé Sáàmù 133:1-3 BYB2014 - Bible AI

1Kíyèsí, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.

2Ó dàbí òróró ìkúnra iyebíye ní orí, tí ó ṣàn dé irungbọ̀n, àní irungbọ̀n Árónì: tí ó sì ṣàn sí etí aṣọ sórí Rẹ̀;

3Bí irì Hémónì tí o ṣàn sórí òke Síónì: nítorí níbẹ̀ ní OLÚWA gbé pàṣẹ ìbùkún, àni ìyè láéláé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>