1Ẹ yìn OLÚWA, ẹ yìn orúkọ OLÚWA; Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ OLÚWA.
2Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé OLÚWA, nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
3Ẹ yin OLÚWA: nítorí tí OLÚWA ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ̀; ní torí tí ó dùn.
4Nítorí tí OLÚWA ti yàn Jákọ́bù fún ara Rẹ̀; àní Ísírẹ́lì fún ìṣúra ààyò Rẹ̀.
4
5Nítorí tí èmi mọ̀ pé OLÚWA tóbi, àti pé OLÚWA jù gbogbo òrìṣà lọ.
6Ohunkóhun tí ó wu OLÚWA, Òun ní iṣe ní ọ̀run, àti ní ayé, ní òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
7Ó mú ìkuku góke láti òpin ilẹ̀ wá: ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjo: ó ń mú afẹ́fé ti inú ilẹ̀ ìṣúra Rẹ̀ wá.
7
8Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Éjíbítì, àti tí ènìyàn àti ti ẹranko.
9Ẹni tí ó rán àmì àti iṣẹ ìyanu sí àrin Rẹ̀, ìwọ Éjíbítì, sí ara Fáráò, àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ gbogbo.
10Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11Síónì, ọba àwọn ará Ámorì, àti Ógù, ọba Báṣánì, àti gbogbo ìjọba Kénánì:
12Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní, ìní fún Ísírẹ́lì, ènìyàn Rẹ̀.
13OLÚWA orúkọ Rẹ dúró láéláé; ìrántí Rẹ OLÚWA, láti ìran-díran.
14ⓐ Nítorí tí OLÚWA yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀, yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
14
15Sílífà Òun wúrà ní èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn.
16Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọ́n kò sọ̀rọ; wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
17Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́ràn; bẹ́ẹ̀ ni kò si èèmí kan ní ẹnu wọn
18Àwọn tí ó ṣe wọn dàbí wọn: bẹ́ẹ̀ sì ní olúkùlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé wọn.
18
19Ẹ̀yin ara ilé Ísírẹ́lì, ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA, ẹ̀yin ará ilé Árónì, fi ìbùkún fún OLÚWA.
20Ẹ̀yin ará ilé Léfì, fi ìbùkún fún OLÚWA; ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù OLÚWA, fi ìbùkún fún OLÚWA.
21Olùbùkún ní OLÚWA, láti Síónì wá,
21tí ń gbé Jérúsálẹ́mù. Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA.