Ìwé Sáàmù 136:1-26 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

2Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:

2nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

3Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA àwọn OLÚWA,

3nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

4Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;

4nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

5Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;

5nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

6ⓐ Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;

6nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

7ⓑ Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;

7nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé

8Òòrùn láti jọba ọ̀sán;

8nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

9Òsùpá àti ìràwọ̀ láti jọba òru;

9nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

10ⓒ Fún ẹni tí ó kọlu Éjíbítì lára àwọn àkọ́bí wọn;

10nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

11ⓓ Ó sì mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàrin wọn;

11nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

12Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;

12nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

13ⓔ Fún ẹni tí ó pín òkun pupa ní ìyà;

13nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

14Ó sì mú Ísírẹ́lì kọjá láàrin Rẹ̀

14nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

15Ṣùgbọ́n ó bi Fáráò àti ogun Rẹ̀ ṣubú nínú òkun pupa;

15nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

16Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn Rẹ̀ la ihà já

16nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

17Fún ẹni tí ó kọ lu àwọn ọba ńlá;

17nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

18Ó sì pa àwọn ọba olókìkí

18nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

19Síónì, ọba àwọn ará Ámórì

19nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

20Àti Ógù, ọba Báṣánì;

20nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

21Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní,

21nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

22Ìní fún Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ Rẹ̀,

22nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

23Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;

23nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

24Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;

24nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

25Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo

25nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

26Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

26nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>