Ìwé Sáàmù 137:1-9 BYB2014 - Bible AI

1Ní ẹ̀bá odò Bábílónì, níbẹ̀ ní àwa gbé jókòó àwa sì sunkún nígbà tí àwa rántí Síónì.

2Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílóò, tí ó wà láàrin Rẹ̀.

3Nítorí pé níbẹ̀ ní àwọn tí ó kó wa ní ìgbékùn bèèrè orin lọ́wọ́ wá, àti àwọn tí ó ni wá lára bèèrè ìdárayá wí pé; ẹ kọ orin Síónì kan fún wa.

4Àwa o ti ṣe kọ orin OLÚWA ni ilẹ̀ àjèjì

5Jérúsálẹ́mù, bí èmi bá gbàgbé Rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò Rẹ.

6Bí èmi kò bá rántí Rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi; bí èmi kò bá fi Jérúsálẹ́mù ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo.

6

7OLÚWA rántí ọjọ́ Jérúsálẹ́mù, lára àwọn ọmọ Édómù, àwọn ẹni tí ń wí pé, wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ de ìpílẹ̀ Rẹ̀!

7

8Ìwọ, ọmọbìnrin Bábílónì, ẹni tí a o parun; ìbùkún ní fún ẹni tí ó san án fún ọ bí ìwọ ti rò sí wa.

9Ìbùkún ní fún ẹni tí ó mú tí ó sì fi ọmọ wẹ́wẹ́ Rẹ̀ ṣán òkúta.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>