1Èmi yóò yìn ọ́ tinú tinú mi gbogbo; níwájú àwọn òrìṣà ní èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ Rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ àti òtítọ́ Rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ Rẹ ga ju orúkọ Rẹ lọ.
3Ní ọjọ́ tí mo képè ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
3
4Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, OLÚWA, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ
5Nítòótọ́, wọn o máa kọrin ní ipa ọ̀nà OLÚWA; nítorí pé ńlá ní ògo OLÚWA.
6Bí OLÚWA tilẹ̀ ga, ṣíbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n agbéraga ní ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di àyè; ìwọ ó nà ọwọ́ Rẹ̀ si àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì gbà mí.
8OLÚWA yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé; OLÚWA, àánú Rẹ̀ dúró láéláé; Má ṣe kọ isẹ́ ọwọ́ ara Rẹ̀ sílẹ̀.