Ìwé Sáàmù 139:1-24 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.

2Ìwọ mọ̀ ìjòkòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ ìrò mi ní ọ̀nà jnijin réré.

3Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi kán àti idùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mímọ̀ fún ọ.

4Nítorí ti kò si ọ̀rọ kan ní ahọ́n mi, kíyèsíi, OLÚWA, ìwọ mọ̀ ọ́n pátapáta.

5Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ Rẹ lé mi.

6Irú ìmọ̀ yìí ṣe ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀.

6

7Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ní ọwọ́ ẹ̀mí Rẹ? Tàbí níbo ní èmi yóò sáré kúrò níwájú Rẹ?

8Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsí i, ìwọ wà níbẹ̀.

9Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin òkun;

10Àní níbẹ̀ náà ni ọwọ́ Rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì dì mí mú.

10

11Bí mo bá wí pé, ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.

12Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọdọ̀ Rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

12

13Nítorí ìwọ ní ó dá ọkàn mi; ìwọ ní ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.

14Èmi yóò yìn ọ nítorí tẹ̀rùtẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní isẹ́ Rẹ; èyí nì ní ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú

15Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọdọ̀ Rẹ, nígbà tí á dá mi ní ìkọ̀kọ̀, tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.

16Ojú Rẹ̀ ti rí ohun ara mi tí ó wà láìpé: àti nínú ìwé Rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn sí, ní ojojumọ́ ni a ń dá wọn, nígbà tí ọ̀kan wọn kò tí i sí.

16

17Ọlọ́run, ìrò inú Rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó!

18Èmi ibá kà wọ́n, wọ́n jù iyanrin lọ ní iye: nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ Rẹ̀ ṣíbẹ̀

19Ọlọ́run ibá jẹ pa àwọn ènìyàn búburú ní tòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹ̀jẹ̀.

20Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ, àwọn ọ̀tá Rẹ ń pe orúkọ Rẹ ní aṣán!

21OLÚWA, ǹjẹ́ èmi kò korìíra àwọn tó korìíra Rẹ? Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?

22Èmi korìíra wọn ní àkótán; èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.

22

23Ọlọ́run, wádíì mi, kí ó sì mọ ọkàn mí; dán mi wò, kí ó sì mọ ìrò inú mi

24Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú kan bá wà nínú mi kí ó sì fi ẹṣẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>