1ⓐ ⓑ Asiwèrè wí nínú ọkàn Rẹ̀ pé, “kò sí Ọlọ́run.” Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú; kò sí ẹnìkan tí ó ṣe rere.
2OLÚWA sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
3Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́; kò sì sí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
3
4Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní kọ́ ẹ̀kọ́: àwọn tí ó ń pa ènìyàn mí jẹ bí ẹníjẹ àkàrà tí wọn kò sì ké pe OLÚWA?
5Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù, nítorí OLÚWA wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
6Ẹ̀yin olùṣe búburú ba èrò àwọn aláìní jẹ́, ṣùgbọ́n OLÚWA ni ààbò wọn.
6
7Ìgbàlà àwọn Ísírẹ́lì yóò ti Síónì wá! Nígbà tí OLÚWA bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jákọ́bù kí ó yọ̀, kí inú Ísírẹ́lì kí ó dùn!