Ìwé Sáàmù 140:1-13 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mi lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà nì;

2Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn; nígbàgbogbo ní wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.

3Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ́ ní abẹ́ ètè wọn.

3

4OLÚWA, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú; yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì ẹni tí ó ti pinnu Rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú

5Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn: wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bá ọ̀nà; wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.

5

6Èmi wí fún OLÚWA pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; OLÚWA, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7Ọlọ́run OLÚWA, agbára ìgbàlà mí, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.

8OLÚWA, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún ún; Má ṣe kún ọgbọ́n búburú Rẹ̀ lọ́wọ́; kí wọn kí ó máa baà gbé ara wọn ga.

8Sela

9Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi kákiri ni, jẹ́ kí ìka ètè ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.

10A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára: Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná, sínú ọ̀gbun omi jínjìn, kí wọn kí ó má bà le dìde mọ́.

11Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹṣẹ̀ múlẹ̀ ní ayé; ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.

11

12Èmi mọ̀ pé, OLÚWA yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò si ṣe ètò fun àwọn tálákà

13Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ Rẹ; àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú Rẹ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>