Ìwé Sáàmù 141:1-10 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi. Gbọ ohun mi, nígba ti mo ba n ké pè ọ́.

2Jẹ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú Rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si okè rí bí i, ẹbọ àsàálẹ́.

2

3Mú kí ìsṣ ṣọ́ ẹnu mi, OLÚWA: kí o sọ̀ máa pa ilẹ̀kùn ètè mi mọ́.

4Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi, Láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ́ àdídùn wọn.

4

5Jẹ́ kí olódodo lù mí: ìṣeun ni ó jẹ́: jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi. Tí kì yóò fọ́ mí ní orí.

5Ṣíbẹ̀ àdúrà mi wá láí sí ìṣe àwọn olùṣe búburú

6A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta, àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.

7Egungun wa tàn kálẹ̀ ni ẹnu isà òkú, Bí ẹni tí ó ń tilẹ̀ tí ó sì ń la ilẹ̀,

7

8Ṣùgbọ́n ojú mi wá ẹ, OLÚWA, Ọlọ́run; nínú Rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe mú mi fún ikú.

9Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi, kúrò nínú ìdẹkùn tí àwọn olùṣe búburú ti dẹ sílẹ̀.

10Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn, nígbà tí èmi kọjá láìléwu.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>