1Èmi kígbe sókè sí OLÚWA; Èmi gbé ohùn mi sókè sí OLÚWA fún àánú.
2Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú Rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú Rẹ̀.
2
3Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣààrẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
4Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì wò ó kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún mi èmi kò ní ààbò; kòsí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún ayé mi.
4
5Èmi kígbe sí ọ, OLÚWA: èmi wí pe, “ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè”
6Fi etí sí igbe mi, nítorí tí èmi wà nínú àníìrètí gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi, nítorí wọ́n lágbára jù mi lọ
7Mú mi jáde kúrò nínú túbú, kí èmi lè máa yin orúkọ Rẹ.
7Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò péjọ nípa mi nítorí iwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ba mi ṣe.