1OLÚWA gbọ̀ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo Rẹ wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
2ⓐ Má ṣe mú ìránṣẹ́ Rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè tí ó ṣe òdodo níwájú Rẹ.
2
3Ọ̀ta ń lé pa mi, ó fún mi pa mọ́ ilẹ̀; ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
4Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi; ọkàn mi tí ó wà nínú mi dààmú.
4
5Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ Rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ Rẹ ti ṣe.
6Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òrùgbẹ Rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀.
6Sela
7Dámilóhùn kánkán, OLÚWA; ó Rẹ̀ ẹ̀mí mi Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lára mi tàbí èmi yóò dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
8Jẹ́ kí òwúrọ̀ mú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí kì í kùnà wá fún mi, nítorí èmi ti gbẹ́kẹ̀ mi lé ọ. Fí ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí sí ọ ni èmi gbé ọkàn mi sókè.
9Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, OLÚWA, nítorí èmi fí ara mi pamọ́ sínú Rẹ̀.
10Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ Rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
10
11Nítorí orúkọ Rẹ, OLÚWA, sọ ayé mi di ààyè; nínú òdodo Rẹ mú mi jáde nínú wàhálà.
12Nínú ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀ta mi kúrò, run gbogbo àwọn ọ̀tá mi, nítorí èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ.