Ìwé Sáàmù 144:1-15 BYB2014 - Bible AI

1Ìyìn sí OLÚWA àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, àti ìka mi fún ìjà.

2Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi, ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó tẹ́rí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi

3OLÚWA, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún-ún, tàbi ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa Rẹ̀?

4Ènìyàn rí bí èmi; ọjọ́ Rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

4

5Tẹ ọ̀run Rẹ ba, OLÚWA, kí o sì sọ̀kalẹ̀; tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí, rú èéfín.

6Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀ta ká; ta ọfà Rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.

7Na ọwọ́ Rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga; gbà mí kí ó sì yọ mí nínú ewu kúrò nínú omi ńlá: kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.

8Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.

8

9Èmi yóò kọ orin túntún sí ọ Ọlọ́run; lára ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá èmi yóò kọ orin sí ọ

10Sí ẹni tí ó fún àwọn ọba ní ìsẹ́gun, ẹni tí ó gba Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ pípanirun.

10

11Gbàmí kí ó sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.

12Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbin tí ó dàgbà ni ìgba èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

13Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:

14Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má síi igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.

14

15Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, Ayọ̀ ni fún àwọn tí ẹni ti Ọlọ́run OLÚWA ń ṣe.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>