Ìwé Sáàmù 145:1-21 BYB2014 - Bible AI

1Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi; Èmi yóò yin orúkọ Rẹ̀ láé àti láéláé

2Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́ èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Rẹ láé àti láéláé.

2

3Títóbi ni OLÚWA. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀: kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi Rẹ̀.

4Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ Rẹ dé ìran mìíràn; wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára Rẹ

5Wọn yóò máa sọ ìyìn ọlá ńlá Rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu Rẹ.

6Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára Rẹ tí ó ní ẹ̀rù èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá Rẹ̀.

7Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà rere Rẹ àti orin ayọ̀ òdodo Rẹ.

7

8Olore òfẹ́ ni OLÚWA àti aláàánú ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀,

9OLÚWA dára sí ẹni gbogbo; ó ní àánú lóri ohungbogbo tí ó dá.

10Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni yóò máa yìn ọ́ OLÚWA; àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí Rẹ.

11Wọn yóò sọ ògo ìjọba Rẹ wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára Rẹ,

12Kí gbogbo ènìyàn le mọ isẹ́ agbára rẹ̀ àti ola ńlá ìjọba Rẹ tí ó lógo.

13Ìjọba Rẹ ìjọba ayérayé ni, àti ìjọba Rẹ wà ní gbogbo ìran-díran.

14OLÚWA mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.

15Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́, ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ

16Ìwọ sí ọwọ́ Rẹ ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17OLÚWA jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà Rẹ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.

18OLÚWA wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

19Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ṣẹ; ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

20OLÚWA dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni búburú ní yóò parun.

20

21Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn OLÚWA. Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>