Ìwé Sáàmù 146:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA, fi ìyìn fún OLÚWA, ìwọ ọkàn mi

2Èmi yóò yin OLÚWA ní gbogbo ayé mi èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.

2

3Ẹ má ṣe ní ìgbẹkẹ̀lé nínú àwọn ọmọ aládé, àní, ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

4Ẹ̀mí Rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ Rẹ̀: Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:

4

5Ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run Jákọ́bù ń ṣe ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ tí ìrètí Rẹ̀ wà nínú OLÚWA Ọlọ́run Rẹ̀,

6Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn OLÚWA, tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí láéláé

7Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa OLÚWA, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)

8OLÚWA mú àwọn afọ́jú ríran OLÚWA, gbé àwọn tí a Rẹ̀ sílẹ̀ ga OLÚWA fẹ́ràn àwọn olódodo.

9OLÚWA ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

9

10OLÚWA jọba títí láé Ọlọ́run Rẹ, ìwọ Síónì, àti

10fún gbogbo ìran, Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>