Ìwé Sáàmù 147:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA nítorí ohun rere láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa, ó yẹ láti kọrin ìyìn síi.

2OLÚWA kọ́ Jérúsálẹ́mù; O ko àwọn Ísírẹ́lì tí a lé sọnù jọ.

3Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bajẹ́ sàn ó sì di ọgbẹ́ wọn.

3

4Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ ó sì pe ọ̀kọ̀ọkan wọn ní orúkọ

5Títóbi ní OLÚWA wa ó sì pọ̀ ní agbára òye Rẹ̀ kò sì ní òpin.

6OLÚWA wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó Rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

6

7Fi ọpẹ́ kọrin sí OLÚWA fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

8Ó fi ìkuukù bo àwọ sánmọ̀ ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè

9Ó pèṣè oúnjẹ fún àwọn ẹranko àti fún awọn ọmọ àdàbà ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

9

10Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹsin bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin

11OLÚWA ní ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú Rẹ̀.

11

12Yin OLÚWA, ìwọ Jérúsálẹ́mù yin Ọlọ́run Rẹ̀, ìwọ Síónì.

13Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ìbodè Rẹ̀ lágbára; Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ Rẹ̀ nínú Rẹ

14Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè Rẹ̀ òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

14

15Òun sì rán àṣẹ Rẹ̀ sí ayé ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sáré tete.

16Ó fi sino fún ni bi irun àgùntàn ó sì fọ́n ìrì idídì ká bí eérú

17Ó rọ òjò yìnyín Rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú òtútù Rẹ̀

18Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ ó mú kí afẹ́fẹ́ Rẹ̀ fẹ́ ó sì mú odò Rẹ̀ sàn.

18

19Ó sọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ di mímọ̀ fún Jákọ́bù àwọn òfin àti ìlànà Rẹ̀ fún Ísírẹ́lì

20Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀ èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ Rẹ̀ wọn ko mọ òfin Rẹ̀.

20Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>