Ìwé Sáàmù 148:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA láti ọ̀run wá Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga

2Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ángẹ́lì Rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun Rẹ̀

3Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

4Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run

5Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ OLÚWA nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

6Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

6

7Ẹ yin OLÚWA láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú òkun

8Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín ìdí omi àti àwọn ìkùùku, ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;

9Òkè ńlá àti gbogbo òkè kékèké, igi eléso àti gbogbo igi kédárì,

10Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:

11Àwọn ọba ayé àti ènìyàn áye gbogbo àwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn onídájọ́ ayé,

12Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

12

13Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ OLÚWA nítorí orúkọ Rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá ògo Rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run

14Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

14Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>