1Ẹ fi ìyìn OLÚWA. Ẹ kọrin titun sí OLÚWA. Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́
2Jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a jẹ́ kí àwọn ọmọ Síónì kí ó ní ayọ̀ nínú ọba wọn.
3Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ Rẹ̀ jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
4Nítorí OLÚWA ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
5Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá Rẹ̀ kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.
5
6Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn àti idà olójú méjì ní ọ́wọ́ wọn.
7Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀ èdè, àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
8Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn àti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
9Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ Rẹ̀ sí wọn èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀.