1OLÚWA, Ta ni yóò máa gbé nínú àgọ́ mímọ́ Rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ Rẹ?
2Ẹni tí ń rìn déédéé tí ó sì ń sọ òtítọ́, láti inú ọkàn Rẹ̀
3tí kò fi ahọ́n Rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò Rẹ̀ tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì Rẹ̀,
4ní ojú ẹni tí ènìyàn-kénìyàn di gígàn ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLÚWA, Ẹni tí ó búra sí ibi ara Rẹ̀ àní tí kò sì yípadà,
5tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.