1Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ Rẹ̀ Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run Rẹ̀.
2Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára Rẹ̀. Ẹ yìn ín fún títóbi Rẹ̀ tí ó tayọ̀.
3Ẹ fi ohùn ìpè, yìn ín. Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
4Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olokùn àti ìpè yìn ín
5Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè. Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro
6Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin OLÚWA.