2OLÚWA ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.Òun ni àpáta ààbò àti agbára ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
3Mo ké pe OLÚWA, ẹni tí ìyìn yẹ fún,a ó sì gbàmí lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta à mi.
3
4Ìrora ikú yí mi kà,àti ìsàn omi àwọn ènìyàn búbúrú dẹ́rùbà mí.
5Okùn isà òkú yí mi ká,ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
6Nínú ìpọ́njú mo ké pe OLÚWA;Mo sunkún sí OLÚWA mi fún ìrànlọ́wọ́.Láti inú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;ẹkún mi wá sí iwájú Rẹ̀, sí inú etí Rẹ̀.
6
7Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì pẹ̀lú,ìpìlẹ̀, àwọn òkè gíga sì sídìí;wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
8Èéfín ti ihò imú Rẹ̀ jáde wá;Iná ajónirun ti ẹnu Rẹ̀ jáde wá,ẹ̀yin iná bú jáde láti inú Rẹ̀.
9Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀.
10Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;ó ń rá bàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì Rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara Rẹ̀ kákùrúkùrù òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
12Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ̀, àwọ̀sánmà ṣíṣú dudu Rẹ kọja lọpẹ̀lú yìnyín àti ẹyìn iná
13OLÚWA sán àrá láti ọ̀run wá;Ohùn ẹni gíga jùlọ tí ń dún.
14Ó ta àwọn ọfà Rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀ta náà ká,ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
15A sì fi ìṣàlẹ̀ àwọn òkun hàn,a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayénípa ìbáwí Rẹ̀, OLÚWA,nípa fífún èémí ihò imú Rẹ.
16Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga ó sì dì mí mú;Ó fà mí jáde láti inú omi jínjìn.
17Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀ta mi alágbára,láti ọwọ́ àwọn ọ̀ta, ti ó lágbára jù fún mi.
18Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;ṣùgbọ́n OLÚWA ni alàtìlẹ́yìn mi.
19Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;Ó gbà mí nítorí tí ó ní inúdídùn sí mi.
19
20OLÚWA ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi
21Nítorí mo ti pa ọ̀nà OLÚWA mọ́;èmi kò ṣe búbúrú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi
22Gbogbo òfin Rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà Rẹ̀.
23Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Rẹ̀;mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24OLÚWA san ẹ̀ṣan fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú Rẹ̀.
24
25Sí olóòótọ́ ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní olóòtọ́,sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26Sí ọlọ́kan mímọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n o Rẹ̀ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28Ìwọ, OLÚWA, jẹ́ kí fìtílà mikí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
28
29Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, èmi ṣare la ogun lọ;pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan
30Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà Rẹ̀ pé,a ti rídìí ọ̀rọ̀ OLÚWAòun ni àpáta ààbòfún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe OLÚWA?Ta ní àpátà bí kò ṣe OLÚWA wa?
32Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrèó sì mú ọ̀nà mi pé.
33Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín;ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíja;apá mi lè tẹ ọrùn idẹ
35Ìwọ fi àṣà ìṣẹ́gun Rẹ̀ fún mi,ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbé mí sókè;àti ìwà ìpẹ̀lẹ́ Rẹ̀ sọ mi di alágbára àti ẹni ńlá.
36Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ mi di ńlá ní ìṣàlẹ̀ mi,kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
36
37Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi èmi sì bá wọnèmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
38Èmi ṣá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;Wọ́n subú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní amùrè fún ogun náà;ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi
40Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀ta mí padà sí mièmi sì pa àwọn tí ó kóríra mí run.
41Wọ́n kígbé fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí yóò rànwọ́n lọ́wọ́.àní sí OLÚWA, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn
42Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
43Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ́ èdè;àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí.
44Wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n gbọ́ gbàmí;àwọn ọmọ àjèjì yóò fi ẹ̀tàn tẹríba fún mi.
45Àyà yóò pá àlejò;wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
45
46OLÚWA wà láàyè! Olùbùkún ni àpáta mi!Gbígbé ga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
46
47Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
48tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.Ìwọ gbé mi ga ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ;lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
49ⓑ Títí láéláé èmi yóò máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ OLÚWA;Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ Rẹ.
50Ó fún Ọba Rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;ó fi ìkáànú àìṣẹ̀tàn fún ẹni-àmì-òróró Rẹ̀,fún Dáfídì àti ìran Rẹ̀ títí láé.