1Àwọn òrun ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;Àwọ̀sánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀.
2Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
3Kò sí ohùn tàbí èdèníbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
4ⓐ Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayéọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé,ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
5Ti o dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá Rẹ̀ wáÒun yọ bí alágbára ọkùnrin tí o ń sáré ìje.
6Ìjáde lọ Rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wáàti àyíká Rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ Rẹ̀;kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore Rẹ̀.
6
7Pípé ni òfin OLÚWA,ó ń yí ọkàn padà.ẹ̀rí OLÚWA dánilójú,ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8Ìlànà OLÚWA tọ̀nà,ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.àṣẹ OLÚWA ní mímọ́,ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
9Ìbẹ̀rù OLÚWA mọ́,ó ń faradà títí láéláé.Ìdájọ́ OLÚWA dájúòdodo ni gbogbo wọn.
10Wọn ṣọ̀wọ́n ju gólùù lọ,ju góòlù tí o dára jùlọ.wọ́n dùn ju oyin lọ,Àti ju afárá oyin lọ.
11Nípa wọn ni a ti sí ìránṣẹ́ Rẹ̀ létí;nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
11
12Ta ni o lé mọ àṣìṣe Rẹ̀?Dáríjìn mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13Wẹ ìrànsẹ́ Rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;Má ṣe jẹ kí wọn kí ó jọba lórí mi.Nígbà náà ní èmí yóò dúró ṣinṣin,èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
13
14Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mikí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú Rẹ,Ìwọ OLÚWA, àpáta mi.àti Olùdáǹdè mi.