1 ⓐ Èéṣe tí àwọn orílẹ̀ èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkísí asán?
2 Àwọn ọba ayé péjọ pọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí OLÚWA àti sí Ẹni àmì òróró Rẹ̀.
3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,” “kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
3
4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; OLÚWA fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Nígbà náà ni ó bá wọn wí ní ìbínú Rẹ̀ ó sì dẹ́rùba bà wọ́n ní ìrunú Rẹ̀, ó wí pé,
6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò lórí Síónì, òkè mímọ́ mi.”
6
7 ⓑ Èmi yóò sì kéde ìpinnu OLÚWA: Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí, èmi ti di baba Rẹ.
8 ⓒ Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè di ìní Rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún Rẹ.
9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómú wómú bí ìkòkò amọ̀”.
9
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n; ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ ṣin OLÚWA pẹ̀lú ìbẹ̀rù ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú kí ó má ba à payin run ní ọ̀nà yin, nítorí ìbínú Rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi i ṣe ibi ìsádi wọn.
Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide