1Kí OLÚWA kí ó gbóhùn Rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jákọ́bù kí ó dáàbòbò ọ́.
2Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Síónì wá.
3Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ ọrẹ Rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun un Rẹ.
3Sela
4Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn Rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ Rẹ ṣẹ.
5Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè Rẹ̀ ṣẹ.
5
6Nisinsìnyí, èmi mọ̀ wí pé OLÚWA pa ẹni-àmí-òróró Rẹ̀ mọ́; yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ Rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀.
7Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin, ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ OLÚWA Ọlọ́run wa.
8Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọn sì ṣubú, ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
8
9OLÚWA, fi ìṣẹ́gun fún ọba! Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!