1OLÚWA ni Olùsọ́ àgùntàn mi, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2ⓐ Ó mú mi dùbúlẹ̀ síbi pápá oko tútù Ó mú mi lọ síbi omí dídákẹ́ rọ́rọ́;
3Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò Ó mú mi lọ sí ọ̀nà ododo nítorí orúkọ Rẹ̀.
4Bí mo tílẹ̀ ń rìn Láàrin àfonífojì òjiji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú ù mi; ọ̀gọ Rẹ àti ọ̀pá à Rẹ wọ́n ń tù mi nínú.