Ìwé Sáàmù 24:1-10 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ti OLÚWA ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún Rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú Rẹ̀;

2Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ Rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun ó sì gbée kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

2

3Ta ni yóò gun òrí òkè OLÚWA lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ Rẹ̀?

4ⓑ Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn Rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.

5Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ OLÚWA, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà Rẹ̀.

6Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀, Ọlọ́run Jákọ́bù.

6Sela

7Ẹ gbé orí yín sókè, Áà! Ẹ̀yin ọ̀nà; Kí á sì gbe yín sókè, áà! Ẹyin ilẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.

8Ta ni ọba ògo náà? OLÚWA tí ó lágbára tí ó sì le, OLÚWA gan-an, tí o lágbára ní ogun.

9Gbé orí yín sókè, áà! Ẹ̀yin ọ̀nà; Kí a sì gbé yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, Kí ọba ògo le è wọlé wá.

10Ta ni ọba ogo náà? OLÚWA àwọn ọmọ ogun Òun ni ọba ògo náà.

10Sela

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>