1OLÚWA, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
2Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀ta mi ó yọ̀ mí.
3Ẹni tí ó dúró tì ọ́; ojú kí yóò tìí àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì.
3
4Fi ọ̀nà Rẹ hàn mí, OLÚWA, kọ mi ní ipa tìrẹ;
5ṣe amọ̀nà mi nínú ọ̀títọ́ ọ Rẹ, kí ò si kọ́ mi, Nítoríi ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6Rántí, áà! OLÚWA àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ̀ ńlá, torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
7Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi tàbí ìrékọjáà mi; gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ rántíì mi nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! OLÚWA.
7
8Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní OLÚWA: nítorí náà ó kọ́ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ni ọ̀nà náà.
9Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà Rẹ̀.
10Gbogbo ipa ọ̀nà OLÚWA ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin, fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí Rẹ̀ mọ́.
11Nítorí orúkọ Rẹ̀, áà! OLÚWA, dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí, nítorí tí ó tóbi.
12Àwọn wo ni ó bẹ̀rù OLÚWA? Yóò kọ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14OLÚWA fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u Rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú Rẹ̀ di mímọ̀ fún wọn.
15Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ OLÚWA, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
15
16Yípadà sími, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkàn wà, mo sì di olùpọ́njú.
17Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú ù mi.
18Kíyèsí ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn.
19Kíyẹ̀sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìírá a mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
20Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
21Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́.
21
22Ra Ísírẹ́lì padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro Rẹ̀!