Ìwé Sáàmù 27:1-14 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? OLÚWA ni ibi olódì ẹ̀mí mi, ta ni ẹni tí èmi yóò bẹ̀rù?

2Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran ara mi, àní àwọn ọ̀ta mi àti àwọn abínúkú ù mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

3Bí ọmọ ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

3

4Ohun kan ni mo bèèrè nípasẹ̀ OLÚWA, òun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé OLÚWA ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsí ẹwà OLÚWA, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹ́ḿpìlì Rẹ.

5Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ Rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ Rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

6Ní ìsinsin yìí a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá a mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rúbọ nínú àgọ́ Rẹ ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí OLÚWA.

6

7Gbọ́ ohùn mi nígbà tẹ́mi báà ń pè, Áà OLÚWA, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;

8“Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u Rẹ̀” Ojú ù Rẹ, OLÚWA, ni èmí ń wá,

9Má ṣe fi ojú Rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, má ṣe fi ìbínú ṣá ìránṣẹ́ Rẹ tì; ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi, Má ṣe ju mi sílẹ̀, má si ṣe kọ̀ mí, áà Ọlọ́run ìgbàlà mi.

10Bí ìyá àti bàbá bá kọ̀ mí sílẹ̀, OLÚWA yóò tẹ́wọ́ gbà mí.

11Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, OLÚWA, kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú nítorí àwọn ọ̀tá mi.

12Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi lọ́wọ́, nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi, wọ́n sì mí ìmí ìkà.

12

13Èmi ní ìgbàgbọ́ pé èmi yóò rí ìre OLÚWA ní ilẹ̀ alààyè.

14Dúró de OLÚWA; kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le àní dúró de OLÚWA.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>