1Ìwọ OLÚWA, mo képe àpáta mi; Má ṣe kọ eti dídi sí mi. Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
2Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú, bí mo ṣe ń ké pé ọ́ fún ìràn lọ́wọ́, bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè sí ibi mímọ́ Rẹ jùlọ.
2
3Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti, pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
4Ṣan ẹ̀ṣan wọn gẹ́gẹ́ bí isẹ́ wọn àti fún iṣẹ́ ibi wọn; gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn; kí o sì san ẹ̀ṣan wọn bí ó ti tọ́.
5Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLÚWA sí, tàbí àwọn isẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ òun ó rún wọn wọlẹ̀ kò sì ní tún wọn kọ́ mọ́.
5
6Alábùkún fún ni OLÚWA! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7OLÚWA ni agbára mi àti aṣà mi; nínú Rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́. ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àni pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
7
8OLÚWA ni agbára àwọn ènìyàn Rẹ̀ òun ni odi ìgbàlà àwọn àyànfẹ́ẹ Rẹ̀.
9Ìwọ gba àwọn ènìyàn Rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún Rẹ; di olùsọ́ àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.