Ìwé Sáàmù 29:1-11 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ fi fún OLÚWA, ẹ̀yin ìran ọ̀run, Ẹ fi fún OLÚWA, ògo àti agbára.

2Fi fún OLÚWA, àní ògo orúkọ Rẹ̀; sin OLÚWA nínú ẹwà ìwà mímọ́.

2

3Ohùn OLÚWA ré àwọn omi kọjá; Ọlọ́run ògo sán àrá, OLÚWA náà, alágbára ń bẹ lóríi omi púpọ̀.

4Ohùn OLÚWA ní agbára; ohùn OLÚWA kún fún ọláńlá.

5Ohùn OLÚWA fọ́ igi kédárì; OLÚWA náà ló fọ́ igi kédárì Lébánónì.

6Ó mú Lébánónì fo bí i ọmọ màlúù, àti Síríónì bí ọmọ àgbáǹréré.

7Ohùn OLÚWA ń ya bí ọwọ́ iná mọ̀nà

8Ohùn OLÚWA ń mi ihà. OLÚWA mi ihà Kádéṣì.

9Ohùn OLÚWA ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀rín bí ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòòhò. àti nínú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

9

10OLÚWA jókòó, Ó sì jọba lórí ìṣàn omi; OLÚWA jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba títí láéláé.

11Kí OLÚWA fi agbára fún àwọn ènìyàn Rẹ̀; bùkún àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>