1Àdúrà Dáfídì Nígbà Tí ó Ṣá Fún Ọmọ Rẹ̀ Ábúsálómù OLÚWA, báwo ni àwọn ọ̀ta mi ṣe pọ̀ tó! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò ní gbà á là.”
2
3Ṣùgbọ́n ìwọ ni àṣà yí mi ká, OLÚWA; iwọ fi ogo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4OLÚWA ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ Rẹ̀ wá.
5Èmi dúbùú lẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí OLÚWA ni ó ń gbé mi ró.
5
6Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
6
7Dìde, OLÚWA! Gbà mí, Ọlọ́run mi! Lu gbogbo àwọn ọ̀ta mi ní àgbọ̀n; kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
7
8Láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ni ìgbàlà ti wá. Kí ìbùkún Rẹ̀ wà lóri àwọn ènìyàn Rẹ̀.