Ìwé Sáàmù 32:1-11 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí ìrékọjá wọn jìn, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

3Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó dànù nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

4Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ Rẹ̀ wúwo sími lára; agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn

4Sela

5Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìsòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún OLÚWA,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí.

5Sela

6Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ ní ìgbà tí a le ri ọ; nitòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè, wọn kì yóò le dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

7Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi; ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu; ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka.

7Sela

8Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ Rẹ lé ọ̀nà ìwọ yóò rìn èmi yóò máa gbà ọ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.

9Má ṣe dàbí ẹsin tàbí ìbaka, tí kò ní òye ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀, kí wọn má ba à sún mọ́ ọ.

10Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìfẹ́ OLÚWA tí ó dúró ṣinṣin ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OLÚWA ká.

10

11Ẹ yọ̀ nínú OLÚWA, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo; ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>