Ìwé Sáàmù 33:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Ẹyọ̀ nínú OLÚWA, ẹ̀yin olódodo ìyín si yẹ fún ẹnidídúró ṣinṣin.

2Ẹyin OLÚWA pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.

3Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin síi, pẹ̀lú ariwo ńlá.

3

4Nítorí pé ọ̀rọ̀ OLÚWA dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.

5Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú OLÚWA.

6Nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ OLÚWA ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu Rẹ̀.

7Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú sí ilé ìṣúra gbogbo.

8Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù OLÚWA: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù Rẹ̀.

9Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.

10OLÚWA ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀ èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákìí.

11Ìgbìmọ̀ OLÚWA dúró títí ayérayé, àní ìrò inú Rẹ̀ láti ìrandíran ni.

11

12Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè náà Ọlọ́run ẹni tí OLÚWA jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní Rẹ̀.

13OLÚWA wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.

14Níbi tí ó ti jókòó lóríi ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé

15ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsí ìṣe wọn.

16A kò gba ọba kan là nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá Rẹ̀.

17Ohun asán ni ẹṣin fún ìsẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá Rẹ̀ gba ni sílẹ̀.

18Wòó ojú OLÚWA wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ Rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin,

19Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láàyè lọ́wọ́ ìyàn.

19

20Ọkàn wa dúró de OLÚWA; òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti aṣà wa.

21Ọkàn wa yọ̀ nínú Rẹ̀, nítorí pé, àwa gba orúkọ mímọ́ Rẹ̀ gbọ́

22Kí àánú Rẹ, OLÚWA, kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú Rẹ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>