1Èmi yóò máa fi ìbùkún fún OLÚWA nígbà gbogbo; ìyìn Rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú OLÚWA; jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3Gbé OLÚWA ga pẹ̀lú mi; kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ Rẹ̀ lékè.
4Èmi wá OLÚWA, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5Wọ́n wòó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn; ojú kò sì tì wọ́n
6Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, OLÚWA sì gbóhùn Rẹ̀; ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀.
7Ángẹ́lì OLÚWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ká ó sì gbà wọ́n.
7
8Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé OLÚWA dára; ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú Rẹ̀.
9Ẹ bẹ̀rù OLÚWA, ẹ̀yin ènìyàn Rẹ̀ mímọ́, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.
10Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n; ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá OLÚWA kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi; èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù OLÚWA.
12ⓐ Taa ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀; kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13Pa ahọ́n Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè Rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere; wá àlàáfíà, kí o sì lépa Rẹ̀.
14
15Ojú OLÚWA ń bẹ lára àwọn olódodo; etí i Rẹ̀ sì sí sí ẹkún wọn.
16Ojú OLÚWA korò sí àwọn tí ń ṣe búburú; láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
16
17Nígbà tí Olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, OLÚWA a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18OLÚWA sún mọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí i ṣe oníròra ọkàn là.
18
19Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n OLÚWA gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo Rẹ̀.
20Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́; kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
20
21Ibi ni ó mú ikú ìkà wá, àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22OLÚWA ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ padà; kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀le tí yóò jẹ̀bi.