Ìwé Sáàmù 35:1-28 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí; kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!

2Di aṣà àti àpáta mú, kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!

3Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi; sọ fún ọkàn mi pé, “Èmi ni ìgbàlà Rẹ.”

4Kí wọn kí ó dààmú, kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú: kí a sì mú wọn padà, kí a sì dààmú àwọn tí ń gbérò ìpalára mi.

5Jẹ́ kí wọn dà bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́, kí ángẹ́lì OLÚWA kí ó máa lé wọn kiri.

6Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó sókùnkùn kí ó sì máa yọ́, kí áńgẹ́lì OLÚWA kí ó máa lépa wọn!

7Nítorí pé, ní àìnídìí ní wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi, ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò fún ọkàn mi.

8Jẹ́ kí ìparun kí ó wá sí orí wọn lójijì. Àwọ̀n Rẹ̀ tí ó dẹ pamọ́, kí ó mú àwọn tìkálára wọn; kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara Rẹ̀.

9Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú OLÚWA, àní ayọ̀ ńlá nínú ìgbàlà Rẹ̀.

10Gbogbo egúngún mi yóò wí pé, “ìwọ OLÚWA, ta ni ó dà bí i Rẹ̀? O gba talákà là lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù wọ́n lọ, talákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

10

11Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde; wọ́n bi mi léèrè àwọn ohun tí èmi kò mọ̀.

12Wọ́n fi búburú san ire fún mi; láti sọ ọkàn mi di òfo.

13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀; mo fi ààwẹ̀ pọ́n ara mi lójú. Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;

14bí i ẹni wí pé ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ní wọ́n; mo ń lọọ́ kiri bí ẹni tí ń sọ̀fọ̀ fún ìyà Rẹ̀, tí o tẹríba nínú ìbànújẹ́.

15Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n kó ara wọn jọ wọ́n sì yọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀ wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.

16Àwọn àgàbàgebè ń ṣe yẹ̀yẹ́ mi ṣíwájú àti sí wájú síi wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.

17Yóò ti pẹ́tó, ìwọ OLÚWA, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ? Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn àní ẹ̀mí i mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.

18Nígbà náà ni èmi yóò sọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá; èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

18

19ⓐ Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń ṣe ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi, tàbí àwọn tí ó kórìírá mi ní àìní dí máa sẹ́jú sí mi.

20Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà, ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.

21Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n sọ wí pé, “Áà! Áà! Ojú wa sì ti rí i.”

21

22Ìwọ́ ti ríi Ìwọ OLÚWA: Má ṣe dákẹ́! Ìwọ OLÚWA, Má ṣe jìnnà sí mi!

23Jí dìde! Ru ara Rẹ̀ sókè fún ààbò mi, fún ìdí mi, Ọlọ́run mi àti OLÚWA mi!

24Dá mi láre, ìwọ OLÚWA, Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo Rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!

25Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Áà! Àti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́: Má ṣe jẹ kí wọn kí ó wí pé, a ti gbé e mì.”

25

26Kí ojú kí ó tì wọ́n, lí wọn kí ó sì dààmú pọ̀, tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.

27Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi fó fún ayọ̀ àti ìdùnnú, kí wọn máa sọ ọ́ titi lọ, pé gbígbéga ni “OLÚWA sí àlàáfíà ìránṣẹ Rẹ̀”.

28Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo Rẹ, àti ìyìn Rẹ ní gbogbo ọjọ́.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>