Ìwé Sáàmù 36:1-12 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ìrékọjá sọ̀rọ̀ sí ènìyàn búburú jinlẹ̀ nínú ọkàn wọn; Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú ojú wọn

2Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.

3Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òun ẹ̀tàn; wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;

4Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn: wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára: wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

4

5Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ, ìwọ OLÚWA, ó ga dé ọ̀run, òtítọ́ ọ̀ Rẹ ga dé àwọ̀sánmà.

6Òdodo Rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run, àwọn ìdájọ́ Rẹ dàbí ibú ńlá; ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, OLÚWA.

7Báwo ni ìṣeun ìdúróṣinṣin ìfẹ́ Rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjijì ìyẹ́ Rẹ.

8Àsè ilé Rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú-dídùn Rẹ.

9Nítorí pé pẹ̀lú ù Rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

9

10Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ Rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́ àti ìgbàlà Rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!

11Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi, kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ni ipò.

12Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé subú sí: a Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>