1Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlàra nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
2nítorí pé wọn yóò gbẹ bí koríko, wọn yóò sì Rẹ̀ dànù bí ewéko tútù
3Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò Rẹ̀
4ṣe inú dídùn sí OLÚWA; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú Rẹ̀.
4
5Fi ọ̀nà Rẹ lé OLÚWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lée pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
6Yóò sì mú kí òdodo Rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ, àti ìdájọ́ Rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
6
7Ìwọ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájú OLÚWA, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
8Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkannú sílẹ̀. Má ṣe ṣe ìkanra, nítorí pé ó gbéni sí búburú pẹ̀lú.
9Nítorí pé á ó gé àwọn ènìyàn búburú kúrò, Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de OLÚWA àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
9
10Ṣíbẹ̀ nígbà díẹ̀ síi,, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́ nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò Rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
11Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
11
12Ènìyàn búburú di rìkísí sí olóòtọ́, wọ́n sì pa ẹyín wọn keke sí wọn;
13Ṣùgbọ́n OLÚWA rẹ́rin-un sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
13
14Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ talákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
15
16Ohun díẹ̀ tí olódodo ní sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú.
17Nítorí pé a ó ṣẹ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n OLÚWA gbé olódodo sókè.
18OLÚWA mọ àwọn ọjọ́ àwọn adúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
19
20Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé, àwọn ọ̀ta OLÚWA yóò dà bí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
21Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san-án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa fi fún ni;
22Nítorí àwọn tí OLÚWA bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
22
23Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá, o si ṣe inú dídùn sí ọ̀nà Rẹ̀;
24Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátapáta, nítorí tí OLÚWA di ọwọ́ Rẹ̀ mú.
25Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmí sì dàgbà; ṣíbẹ̀ èmi kò ì tíi rí ki a kọ olódodo ṣílẹ̀, tàbí kí irú ọmọ Rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsí i fún ni.
26
27Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; nígbà náà ni ìwọ gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28Nítorí pé OLÚWA fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ sílẹ̀.
28Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ní a ó ké kúrò.
29Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà, yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
29
30Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ahọ́n Rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31Òfin Ọlọ́run Rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn; àwọn ìgbẹ́sẹ̀ Rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
31
32Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo, Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33OLÚWA kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi, nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ Rẹ̀.
33
34Dúró de OLÚWA, kí o sì má a pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́, yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà: Nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
35Èmí ti rí ènìyàn búburú tí n hu ìwà ìkà, ó sì fi ara Rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá.
36Ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan síi ó kọjá lọ, sì kíyèsí, kò sì sí mọ́; bi ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
36
37Má a kíyèsí ẹni pípé, kí o sì wo adúró ṣinṣin, nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ní a ó parun papọ̀; ìran àwọn ènìyàn búburú ní a ó gé kúrò.
38
39Ìgbàlà àwọn adúró ṣinṣin wa láti ọ̀dọ̀ OLÚWA: òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40OLÚWA yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n; yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.