Ìwé Sáàmù 39:1-13 BYB2014 - Bible AI

1Mo wí pé, èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀ èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.

2Mo fi ìdákẹ́ ya odi; mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere; ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ síi.

3Àyà mi gbóná ní inú mi, nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, ina ràn; nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀.

3

4OLÚWA, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.

5Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú Rẹ: Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere Rẹ̀ jásí asán pátapáta.

5Sela

6Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

6

7Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, OLÚWA, kín ni mo ń dúró dè? Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Rẹ.

8Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo. Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn àwọn ènìyàn búburú.

9Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́; èmi kò sì ya ẹnu mi, nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.

10Mú ìnà Rẹ̀ kúrò ní ara mi; èmí ṣègbé tán nípa ìlù ọwọ́ Rẹ.

11Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà Rẹ parun bí kòkòrò aṣọ; nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

11

12“Gbọ́ àdúrà mi, OLÚWA, kí o sì fetí sí igbe mi; kí o má ṣe di etí Rẹ sí ẹkún mi nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ Rẹ àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.

13Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára, kí èmi tó lọ kúrò níhín-ín yìí, àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>