Ìwé Sáàmù 40:1-17 BYB2014 - Bible AI

1Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de OLÚWA; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

2Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbesẹ̀ mi wà láìfòyà.

3Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ yóò ríi wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé OLÚWA.

3

4Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n ọn-nì tí ó fi OLÚWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.

5OLÚWA Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn isẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe. Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa; ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn, wọn ju ohun tí ènìyàn leè kà lọ.

5

6ⓐ Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti sí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò bèèrè.

7Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíkà nì a kọ ọ nípa temí wí pé.

8Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi; Òfin Rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

8

9Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà láàrin àwùjọ ńlá; wòó, èmi kò pa ètè mí mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀, ìwọ OLÚWA.

10Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi, èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà Rẹ̀: èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ mọ́ kúrò láàrin àwọn ìjọ ńlá.

10

11Ìwọ má ṣe, fa àánú Rẹ̀ tí ó rọnú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; OLÚWA jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ àti òtítọ́ Rẹ kí ó máa pa mí mọ́ títí ayérayé.

12Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́; wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà.

12

13ⓑ Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ OLÚWA, láti gbà mí là; OLÚWA, yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14Gbogbo àwọn wọ̀nnì ni kí ojú kí ó tì kí wọn kí ó sì dààmú àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun: jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn ki á sì dójú tì wọ́n, àwọn tí n wá ìpalára mi.

15Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Áà! Áá!” ó di ẹni àfọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtijú wọn.

16Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ kí ó máa yọ̀ kí inú wọn sì máa dùn sí ọ; kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà Rẹ kí o máa wí nígbà gbogbo pé, “Gbígbéga ni OLÚWA!”

16

17Bí ó ṣe ti èmi ni, talákà àti aláìní ni èmi, ṣùgbọ́n OLÚWA ń ṣe ìrántí mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti ìgbàlà mi; Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́, ìwọ Ọlọ́run mi.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>