3
4Ní ti èmi, mo wí pé “OLÚWA, ṣàánú fún mí; wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
5Àwọn ọ̀ta mi ń sọ́rọ̀ mi nínú arankan, pé “Nígbà wo ni yóò kú ti orúkọ Rẹ̀ yóò sì run?”
6Nígbà kígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà Rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara Rẹ̀; nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kalẹ̀.
7Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi; èmi ni wọn ń gbìmọ̀ ibi sí,
8wọ́n wí pé “Ohun búburú ni ó di mọ́-ọn sinsin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́”.
9ⓐ Pàápàá ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgíṣẹ̀ Rẹ̀ sókè sí mi.
9
10Ṣùgbọ́n ìwọ OLÚWA, ṣàánú fún mi; gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11Èmi mọ̀ pé inú Rẹ̀ dùn sí mi, nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12Bí ó ṣe tèmi ni ìwọ dì mí mú nínú ìwà òtítọ́ mi ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú Rẹ títí láé.