Ìwé Sáàmù 42:1-11 BYB2014 - Bible AI

1Bí àgbọ̀nrín tí ń mí hẹlẹ sí ìpa odò omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi n mì hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run

2Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè. Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?

3Oúnjẹ mi ní omijé mi ní ọ̀sán àti ní òru, nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́, “Ọlọ́run Rẹ̀ dà?”

4Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí, èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi: èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ, èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

4

5Èéṣe tí o fi n rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi? Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi? Ìwọ ṣe ìrètí ni ti Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sáà máa yìn ín.

5

6Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi: nítorí náà, èmi ó rántí Rẹ láti ilẹ̀ Jọ́dánì wá, láti Hámónì láti òkè Mísárì.

7Ibú omi ń pe ibú omi nípa híhó omi ṣíṣàn Rẹ̀ gbogbo rírú omi àti bíbì omi Rẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀.

7

8Ní ọ̀sán ní OLÚWA ran ìfẹ́ Rẹ̀, àti ni àṣálẹ́ ni orin Rẹ̀ wà pẹ̀lú mi àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

9Èmi wí fún Ọlọ́run àpátà mi, “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi? Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́, nítorí ìnilára ọ̀ta?”

10Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀ta mi ń gàn mí, Bí wọn ti ń béèrè ni gbogbo ọjọ́. “Níbo ni Ọlọ́run Rẹ wà?”

11Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi? Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi? Fi ìrètí Rẹ sínú Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>