Ìwé Sáàmù 44:1-26 BYB2014 - Bible AI

1Àti fi ètí wa gbọ́, Ọlọ́run àwọn baba wa tí sọ fún wa oun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.

2Ìwọ fi ọwọ́ Rẹ̀ lé orílẹ̀-èdè jáde Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; Ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.

3Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọn gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í se apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò se; ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti, apá Rẹ̀; àti ìmọ́lẹ̀ ojú Rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

3

4Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jákọ́bù.

5Nípaṣẹ̀ Rẹ̀ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣúbú; nípasẹ̀ orúkọ Rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá ti ó dìde sí wa mọ́lẹ̀

6Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,

7Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.

8Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́, àwa ó sì yin orúkọ Rẹ̀ títí láé.

8Sela

9Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá; Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.

10Ìwọ ti bá wa jà ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa, àwọn ọ̀ta wa ti gba ilẹ̀ wa, wọ́n sì fi ipá gba oko wa.

11Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárin àwọn aláìkọlà.

12Ìwọ ta àwọn ènìyàn Rẹ fún owó kékeré, Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

12

13Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

14Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè; àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.

15Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́, ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,

16nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ojú àwọn ọ̀ta àti olùgbẹ̀san.

16

17Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ṣíbẹ̀ àwa kò gbàgbé Rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mu Rẹ̀.

18Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà Rẹ̀.

19Ṣùgbọ́n wọ́n kọ lù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ajáko tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

19

20Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.

21Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí Rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kò inú ọkàn?

22ⓐ Ṣíbẹ̀, nítorí Rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

22

23Jí, OLÚWA! Èéṣe tí ìwọ ń sùn? Dìde fún ra Rẹ! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.

24Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú Rẹ mọ́ tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

24

25Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku; ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.

26Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́; ràwápadà nítorí ìfẹ́ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>