1Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
2Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ: a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè: nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
3Gba idà Rẹ mọ́ ìhà Rẹ, ìwọ alágbára jùlọ wọ ara Rẹ̀ ní ògo àti ọla ńlá.
4Nínú ọlá-ńlá Rẹ máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ṣe ohun ẹ̀rù
5Jẹ́ kí ọfà mímú Rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀
6ⓐ Ìjọba Rẹ Ọlọ́run, yóò pẹ́ títí ayé ọ̀pá aládé ni yóò jẹ́ ọ̀pá ìjọba Rẹ
7Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run Rẹ̀ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀, nípa fífí àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́
8Gbogbo aṣọ Rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjíá àti alóe àti kaṣíà; láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú Rẹ̀ dùn.
9Àwọn ọmọbìnrin àwọn aládé wà nínú àwọn àyànfẹ́ Rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró nínú wúrà ófórì.