Ìwé Sáàmù 46:1-11 BYB2014 - Bible AI

1Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nínú ìgbà ìpọ́njú.

2Nítori náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ sí ayé ní ìdí tí òkè sì ṣubú sínú òkun

3Tí omi Rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ̀.

3Sela

4Odò ńlá kan wà tí sísàn Rẹ̀ mú ìnú ìlú Ọlọ́run dùn ibi mímọ́, nibi ti ọ̀gá ògo ń gbé.

5Ọlọ́run wà pẹ̀lú Rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn an lọ́wọ́ ní kùtùkùtù ọ̀wúrọ̀

6Àwọn orílẹ̀ èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba subú ó gbé ohun Rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

6

7Ọlọ́run awọn ọmọ ogún wà pẹ̀lú wa Ọlọ́run Jákọ́bù ni ààbò wa

8Ẹ wá wo iṣẹ́ OLÚWA irú ahoro tí ó ṣe ní ayé

9O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná

10Ẹ dúró jẹ́ẹ kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀ èdè A o gbé mi ga ní ayé.

10

11Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa Ọlọ́run Jákọ́bù sì ni ààbò wa.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>