Ìwé Sáàmù 47:1-9 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀

2Báwo ni OLÚWA ọ̀gá ògo ti ni ẹ̀rù tó ọba ńlá lórí gbogbo ayé

3Ó ṣẹ́ àwọn orílẹ̀ èdè lábẹ́ wa àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa

4Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa ọlá Jákọ́bù, ẹni tí ó fẹ́ wa

5Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀ OLÚWA ti òun ti àriwo ipè

6Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, Ẹ kọrin ìyìn Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, Ẹ kọrin ìyìn!

6

7Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Sáàmù!

8Ọlọ́run jọba lórí gbogbo ayé; Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ Rẹ̀

9Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Ábúráhámù nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni òun ni ó ga jùlọ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>