Ìwé Sáàmù 48:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Ẹni ńlá ní OLÚWA, tí o sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ Rẹ̀

2ⓐ Ó dára nínú ipò ìtẹ́ Rẹ̀ ayọ̀ gbogbo ayé òkè Síónì, ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá.

3Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin Rẹ̀; ó fi ara Rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

4Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀ wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ

5Wọn ríi bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ

6Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀ ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí

7Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Táṣíṣì wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà oorùn.

7

8Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí, Ní ìnú OLÚWA àwọn ọmọ ogun Ní ìlú Ọlọ́run wa Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé.

8Sela

9Láàrin tẹ́ḿpìlì Rẹ, Ọlọ́run àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ Rẹ

10Gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ Ọlọ́run ìyìn Rẹ̀ dé òpin ayé ọwọ́ ọ̀tún Rẹ kún fún òdodo

11Jẹ́ kí òkè Síónì kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin Júdà kí ó dùn nítorí ìdájọ́ Rẹ̀.

11

12Rìn Síónì kiri lọ yíká Rẹ̀, ka ilé ìsọ́ Rẹ̀

13Kíyèsí odi Rẹ̀ kíyèsí àwọn ààfin Rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀

14Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>